5 Bákan náà, Kristi kọ́ ló ṣe ara rẹ̀ lógo + nígbà tó di àlùfáà àgbà, àmọ́ Ẹni tó sọ fún un pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”+ ló ṣe é lógo. 6 Ó tún sọ ní ibòmíì pé, “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+
19 A ní ìrètí yìí+ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn,* ó dájú, ó fìdí múlẹ̀, ó sì wọlé sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+20 níbi tí aṣíwájú kan ti wọ̀ nítorí wa, ìyẹn Jésù,+ ẹni tó ti di àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.+
11 Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ àlùfáà+ àwọn ọmọ Léfì lè mú ìjẹ́pípé wá ni (torí ó wà lára Òfin tí a fún àwọn èèyàn), ṣé a tún máa nílò kí àlùfáà míì dìde, ẹni tí a sọ pé ó wà ní ọ̀nà ti Melikisédékì,+ tí kì í ṣe ní ọ̀nà ti Áárónì?