28 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé,+ kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀,+ kí ẹ máa jọba lórí+ àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.”
26 Láti ara ọkùnrin kan ló ti dá+ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa gbé lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ó yan àkókò fún àwọn nǹkan, ó sì pa ààlà ibi tí àwọn èèyàn á máa gbé,+