29 Tí ẹnì kan bá dìde láti lépa rẹ, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi ẹ̀mí* olúwa mi pa mọ́ sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti ẹ̀mí* àwọn ọ̀tá rẹ, òun yóò ta á jáde bí ìgbà tí èèyàn fi kànnàkànnà ta òkúta.*
12 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Gbogbo ohun tó ní wà ní ọwọ́ rẹ.* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ọkùnrin náà fúnra rẹ̀!” Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà.+
8 Torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, lẹ́yìn tí a ti yìn ín lógo, ó rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń kó ẹrù yín,+ pé; ‘Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú* mi.+
9 Torí náà, Jèhófà* mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò,+ síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun* ní ọjọ́ ìdájọ́,+