ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 6:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ń gbé Àpótí+ Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti ìró ìwo.+

  • Sáàmù 27:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà,

      Òun ni mo sì ń wá, pé:

      Kí n máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+

      Kí n máa rí adùn Jèhófà,

      Kí n sì máa fi ìmọrírì* wo tẹ́ńpìlì* rẹ̀.+

  • Sáàmù 42:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Mo rántí àwọn nǹkan yìí, mo sì tú ọkàn* mi jáde,

      Torí pé, nígbà kan, mo ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rìn;

      Mo máa ń rìn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀* níwájú wọn lọ sí ilé Ọlọ́run,

      Pẹ̀lú igbe ayọ̀ àti ti ọpẹ́,

      Ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń ṣàjọyọ̀.+

  • Sáàmù 84:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nítorí ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbikíbi!+

      Mo yàn láti máa dúró níbi àbáwọlé ilé Ọlọ́run mi

      Dípò kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn èèyàn burúkú.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́