ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 38:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi;+

      Bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé.

  • Sáàmù 103:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa,+

      Ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.+

  • Sáàmù 143:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 143 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+

      Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.

      Dá mi lóhùn nínú òtítọ́ rẹ àti òdodo rẹ.

      2 Má ṣe bá ìránṣẹ́ rẹ ṣẹjọ́,

      Nítorí kò sí alààyè kankan tó lè jẹ́ olódodo níwájú rẹ.+

  • Àìsáyà 55:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+

      Kí ẹni ibi sì yí èrò rẹ̀ pa dà;

      Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀,+

      Sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.*+

  • Dáníẹ́lì 9:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ọlọ́run mi, tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì gbọ́! La ojú rẹ, kí o sì rí ìyà tó ń jẹ wá àti bí ìlú tí a fi orúkọ rẹ pè ṣe di ahoro; kì í ṣe torí àwọn ìṣe òdodo wa la ṣe ń bẹ̀ ọ́, torí àánú rẹ tó pọ̀ ni.+

  • Róòmù 3:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Nítorí náà, kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo níwájú rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin,+ torí òfin ló jẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye nípa ẹ̀ṣẹ̀.+

  • Títù 3:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 (kì í ṣe torí iṣẹ́ òdodo kankan tí a ṣe,+ ṣùgbọ́n torí àánú rẹ̀),+ ó gbà wá là nípasẹ̀ ìwẹ̀ tó mú ká ní ìyè+ àti bó ṣe sọ wá di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́