-
Jóòbù 9:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ló rí.
Àmọ́ báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre tó bá bá Ọlọ́run ṣe ẹjọ́?+
-
-
Oníwàásù 7:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nítorí kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.+
-
-
Gálátíà 2:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 mọ̀ pé kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin ló ń mú ká pe èèyàn ní olódodo, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ nínú Jésù Kristi+ nìkan. Ìdí nìyẹn tí a fi ní ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù, kí a lè pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin, nítorí kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin.+
-
-
1 Jòhánù 1:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Tí a bá sọ pé, “A ò dẹ́ṣẹ̀,” à ń sọ ọ́ di òpùrọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.
-