17 Torí tí àṣemáṣe ọkùnrin kan bá mú kí ikú jọba nípasẹ̀ ẹni náà,+ ǹjẹ́ àwọn tó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ òdodo+ kò ní jọba+ nínú ìyè nípasẹ̀ èèyàn kan, ìyẹn Jésù Kristi?+
11 Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́;+ a ti yà yín sí mímọ́;+ a ti pè yín ní olódodo+ ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run wa.