-
Ìfihàn 5:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan pé: “Ìwọ ló yẹ kó gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, torí pé wọ́n pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn èèyàn fún Ọlọ́run+ látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè,+ 10 o mú kí wọ́n di ìjọba kan+ àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa,+ wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba+ lé ayé lórí.”
-
-
Ìfihàn 20:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.
-