5 àti látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, “Ẹlẹ́rìí Olóòótọ́,”+ “àkọ́bí nínú àwọn òkú,”+ àti “Alákòóso àwọn ọba ayé.”+
Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+— 6 tó sì mú ká di ìjọba kan,+ àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—àní, òun ni kí ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.