15 Àmọ́ ẹ̀bùn náà ò rí bí àṣemáṣe. Torí bó ṣe jẹ́ pé nípa àṣemáṣe ọkùnrin kan ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi kú, ẹ wo bí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ọkùnrin kan,+ ìyẹn Jésù Kristi, ṣe ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní!*+
21 Nítorí kí ni? Kí ó lè jẹ́ pé bí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣe jọba,+ kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè jọba nípasẹ̀ òdodo, kí ó sì yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.+