ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 18:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,

      Mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́.

      Ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,+

      Igbe tí mo ké sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+

  • Jónà 2:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Jèhófà, ìwọ ni Ẹni tí mo rántí nígbà tí ẹ̀mí* mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+

      Ìgbà yẹn ni mo gbàdúrà sí ọ, àdúrà mi sì wọnú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ.+

  • Mátíù 26:38, 39
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”+ 39 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé:+ “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá. Síbẹ̀, kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ bí ìwọ ṣe fẹ́.”+

  • Máàkù 15:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Ní wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” tó túmọ̀ sí: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”+

  • Hébérù 5:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nígbà tí Kristi wà ní ayé,* ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì fi ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé tọrọ+ lọ́wọ́ Ẹni tó lè gbà á lọ́wọ́ ikú, a sì gbọ́ ọ, a ṣojúure sí i torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́