1 Àwọn Ọba 8:66 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀. Sáàmù 13:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti san èrè fún mi lọ́pọ̀lọpọ̀.*+ Sáàmù 31:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Oore rẹ mà pọ̀ o!+ O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ,+O sì ti fi wọ́n hàn lójú gbogbo èèyàn, nítorí àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò.+ Àìsáyà 63:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára. Jeremáyà 31:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+ Wọ́n* á dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+Wọn kò sì ní ráágó mọ́.”+
66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.
19 Oore rẹ mà pọ̀ o!+ O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ,+O sì ti fi wọ́n hàn lójú gbogbo èèyàn, nítorí àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò.+
7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.
12 Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+ Wọ́n* á dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+Wọn kò sì ní ráágó mọ́.”+