Sáàmù 8:3, 4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ,Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀,+ 4 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kànÀti ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+ Àìsáyà 40:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Ẹnì kan wà tó ń gbé orí òbìrìkìtì* ayé,+Àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ sì dà bíi tata,Ó ń na ọ̀run bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ní ihò wínníwínní,Ó sì tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé.+ Róòmù 1:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre.
3 Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ,Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀,+ 4 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kànÀti ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+
22 Ẹnì kan wà tó ń gbé orí òbìrìkìtì* ayé,+Àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ sì dà bíi tata,Ó ń na ọ̀run bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ní ihò wínníwínní,Ó sì tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé.+
20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre.