-
Sáàmù 144:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Jèhófà, kí ni èèyàn jẹ́, tí o fi ń kíyè sí i
Àti ọmọ ẹni kíkú, tí o fi ń fiyè sí i?+
-
-
Mátíù 6:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?
-
-
Hébérù 2:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ ibì kan wà tí ẹlẹ́rìí kan ti sọ pé: “Kí ni èèyàn jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn tàbí ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+ 7 O mú kí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì; o fi ògo àti ọlá dé e ládé, o sì yàn án ṣe olórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 8 O fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Bí Ọlọ́run ṣe fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kò sí ohun tí kò fi sábẹ́ rẹ̀.+ Àmọ́, ní báyìí, a ò tíì rí ohun gbogbo lábẹ́ rẹ̀.+
-