Jóòbù 38:25-27 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+26 Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+27 Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,Kó sì mú kí koríko hù?+ Àìsáyà 30:23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+
25 Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+26 Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+27 Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,Kó sì mú kí koríko hù?+
23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+