16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ pa Sábáàtì mọ́; wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Sábáàtì mọ́ jálẹ̀ gbogbo ìran wọn. Májẹ̀mú tó máa wà títí lọ ni. 17 Ó jẹ́ àmì tó máa wà pẹ́ títí láàárín èmi àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà fi dá ọ̀run àti ayé, ó wá sinmi ní ọjọ́ keje, ara sì tù ú.’”+