24 Torí náà, bí ahọ́n iná ṣe máa ń jó àgékù pòròpórò run,
Tí koríko gbígbẹ sì máa ń rún sínú ọwọ́ iná,
Gbòǹgbò wọn gangan máa jẹra,
Ìtànná wọn sì máa fọ́n ká bí eruku,
Torí pé wọ́n kọ òfin Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Wọn ò sì ka ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sí.+