ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 31:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Tí mo bá mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ tí wọ́n jẹun tẹ́rùn, tí nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn,*+ wọ́n á lọ máa tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, wọ́n á sì máa sìn wọ́n, wọ́n á hùwà àfojúdi sí mi, wọ́n á sì da májẹ̀mú mi.+

  • 2 Àwọn Ọba 17:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Jèhófà lo gbogbo wòlíì rẹ̀ àti gbogbo aríran+ rẹ̀ láti máa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà pé: “Ẹ kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín!+ Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́, bó ṣe wà nínú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, tí mo sì fi rán àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín.” 14 Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọ́n sì ya alágídí bí* àwọn baba ńlá wọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run wọn.+

  • Nehemáyà 9:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+

  • Àìsáyà 1:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 O gbé! Ìwọ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,+

      Àwọn èèyàn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn,

      Ìran àwọn èèyàn burúkú, àwọn ọmọ oníwà ìbàjẹ́!

      Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀;+

      Wọ́n ti hùwà àfojúdi sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì;

      Wọ́n ti kẹ̀yìn sí i.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́