Sáàmù 103:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Bí bàbá ṣe ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.+ Òwe 28:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí,+Àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.+ Àìsáyà 43:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Èmi, àní èmi ni Ẹni tó ń nu àwọn àṣìṣe* rẹ+ kúrò nítorí tèmi,+Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+ Àìsáyà 44:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún. Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+
13 Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí,+Àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.+
22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún. Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+