ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 51:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 51 Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

      Nu àwọn àṣìṣe mi kúrò nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.+

  • Sáàmù 103:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,

      Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+

  • Àìsáyà 1:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+

      “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,

      Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+

      Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,

      Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.

  • Àìsáyà 43:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Èmi, àní èmi ni Ẹni tó ń nu àwọn àṣìṣe* rẹ+ kúrò nítorí tèmi,+

      Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+

  • Jeremáyà 33:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ṣe ni màá wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi,+ màá sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n àti àwọn àṣìṣe wọn.+

  • Ìṣe 3:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì yí pa dà,+ kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,+ kí àwọn àsìkò ìtura lè wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀,*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́