Òwe 4:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Má ṣe gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú,Má sì rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.+ Òwe 13:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+Àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.+ 1 Kọ́ríńtì 15:33 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 33 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere* jẹ́.+