Òwe 13:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+Àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.+ 1 Kọ́ríńtì 5:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Bí ẹ ṣe ń fọ́nnu yìí kò dáa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú ni?+