15 Kò ṣeé fi ògidì wúrà rà;
A kò sì lè díwọ̀n fàdákà láti fi pààrọ̀ rẹ̀.+
16 Kò ṣeé fi wúrà Ófírì rà,+
Kò sì ṣeé fi òkúta ónísì tó ṣọ̀wọ́n àti sàfáyà rà.
17 Wúrà àti gíláàsì kò ṣeé fi wé e;
A kò lè fi ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi wúrà tó dáa ṣe pààrọ̀ rẹ̀.+
18 A ò lè mẹ́nu kan iyùn àti òkúta kírísítálì,+
Torí ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju àpò tí péálì kún inú rẹ̀.