5 Láyé ìgbà Hẹ́rọ́dù,+ ọba Jùdíà, àlùfáà kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sekaráyà nínú ìpín Ábíjà.+ Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Áárónì ni ìyàwó rẹ̀, Èlísábẹ́tì ni orúkọ rẹ̀. 6 Àwọn méjèèjì jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì ń rìn láìlẹ́bi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ àti àwọn ohun tí òfin Jèhófà béèrè.