ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 1:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Nígbà yẹn, mo sọ fún àwọn onídàájọ́ yín pé, ‘Tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, kí ẹ máa fi òdodo ṣèdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbè sápá kan nínú ìdájọ́.+ Bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó kéré ni kí ẹ ṣe gbọ́ ti ẹni ńlá.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn dẹ́rù bà yín,+ torí Ọlọ́run ló ni ìdájọ́;+ tí ẹjọ́ kan bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì gbọ́ ọ.’+

  • 2 Sámúẹ́lì 8:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ Dáfídì ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo+ sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+

  • Sáàmù 72:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,

      Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+

       2 Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ rò,

      Kí ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.+

  • Àìsáyà 11:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*

      Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.

      Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+

      Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́