-
Lúùkù 12:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Torí náà, ó sọ pé, ‘Ohun tí màá ṣe nìyí:+ Màá ya àwọn ilé ìkẹ́rùsí mi lulẹ̀, màá sì kọ́ àwọn tó tóbi, ibẹ̀ ni màá kó gbogbo ọkà mi àti gbogbo ẹrù mi jọ sí, 19 màá sì sọ fún ara* mi pé: “O ní* ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’ 20 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí* rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’+
-