16 Ebi ò ní pa wọ́n mọ́, òùngbẹ ò sì ní gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn ò ní pa wọ́n, ooru èyíkéyìí tó ń jóni ò sì ní mú wọn,+ 17 torí Ọ̀dọ́ Àgùntàn,+ tó wà ní àárín ìtẹ́ náà, máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn,+ ó sì máa darí wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.+ Ọlọ́run sì máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”+