19 Wò ó! Ní àkókò yẹn, màá dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tó ń pọ́n ọ lójú;+
Màá gba ẹni tó ń tiro là,+
Màá sì kó àwọn tó ti fọ́n ká jọ.+
Màá sọ wọ́n di ẹni iyì àti olókìkí
Ní gbogbo ilẹ̀ tí ìtìjú ti bá wọn.
20 Ní àkókò yẹn, màá mú yín wọlé,
Ní àkókò tí mo kó yín jọ.
Nítorí màá sọ yín di olókìkí àti ẹni iyì+ láàárín gbogbo aráyé,
Tí mo bá kó àwọn èèyàn yín tó wà ní oko ẹrú pa dà lójú yín,” ni Jèhófà wí.+