-
Àìsáyà 11:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+ 12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “‘“Èmi fúnra mi yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi,+ èmi fúnra mi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”
-