17 Torí wò ó! Mò ń dá ọ̀run tuntun àti ayé tuntun;+
Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí,
Wọn ò sì ní wá sí ọkàn.+
18 Torí náà, ẹ yọ̀, kí inú yín sì máa dùn títí láé torí ohun tí mò ń dá.
Torí wò ó! Mò ń dá Jerúsálẹ́mù láti mú ayọ̀ wá
Àti àwọn èèyàn rẹ̀ láti jẹ́ orísun ìdùnnú.+