Sáàmù 33:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Àmọ́ àwọn ìpinnu* Jèhófà yóò dúró títí láé;+Èrò ọkàn rẹ̀ wà láti ìran dé ìran. Òwe 19:21 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ń gbèrò nínú ọkàn rẹ̀,Àmọ́ ìmọ̀ràn* Jèhófà ni yóò borí.+ Òwe 21:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.+ Àìsáyà 46:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Màá pe ẹyẹ aṣọdẹ wá láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+Ọkùnrin tó máa ṣe ohun tí mo pinnu*+ máa wá láti ilẹ̀ tó jìn. Mo ti sọ̀rọ̀, màá sì mú kó ṣẹ. Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.+
11 Màá pe ẹyẹ aṣọdẹ wá láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+Ọkùnrin tó máa ṣe ohun tí mo pinnu*+ máa wá láti ilẹ̀ tó jìn. Mo ti sọ̀rọ̀, màá sì mú kó ṣẹ. Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.+