6 Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun,+ àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run;+ 7 àlàáfíà Ọlọ́run+ tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín+ àti agbára ìrònú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.