3 “Fetí sí mi, ìwọ ilé Jékọ́bù àti gbogbo ẹ̀yin tó ṣẹ́ kù ní ilé Ísírẹ́lì,+
Ẹ̀yin tí mò ń tì lẹ́yìn látìgbà tí a ti bí yín, tí mo sì gbé látinú oyún.+
4 Títí o fi máa dàgbà, mi ò ní yí pa dà;+
Títí irun rẹ fi máa funfun, mi ò ní yéé gbé ọ.
Bí mo ti ń ṣe, màá gbé ọ, màá rù ọ́, màá sì gbà ọ́ sílẹ̀.+