Jẹ́nẹ́sísì 49:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+ Sáàmù 2:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Á sọ pé: “Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ+Lórí Síónì,+ òkè mímọ́ mi.” Lúùkù 1:32, 33 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+ Jòhánù 1:49 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 49 Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”+
10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+
32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+