ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 7:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+

  • 2 Sámúẹ́lì 7:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+

  • Sáàmù 132:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,

      Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:

      “Ọ̀kan lára ọmọ* rẹ

      Ni màá gbé gorí ìtẹ́ rẹ.+

  • Àìsáyà 9:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,

      Àlàáfíà kò sì ní lópin,+

      Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,

      Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,

      Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+

      Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

      Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.

  • Àìsáyà 11:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ẹ̀ka igi+ kan máa yọ látinú kùkùté Jésè,+

      Èéhù+ kan látinú gbòǹgbò rẹ̀ sì máa so èso.

  • Àìsáyà 11:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ní ọjọ́ yẹn, gbòǹgbò Jésè+ máa dúró bí àmì* fún àwọn èèyàn.+

      Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè máa yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà,*+

      Ibi ìsinmi rẹ̀ sì máa di ológo.

  • Jeremáyà 23:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+

  • Mátíù 1:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 1 Ìwé ìtàn* nípa Jésù Kristi,* ọmọ Dáfídì,+ ọmọ Ábúráhámù:+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́