-
Diutarónómì 4:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 20:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì.
-