ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 18:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+

  • 2 Kíróníkà 32:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Lẹ́yìn tí Hẹsikáyà ti fi òtítọ́ ṣe àwọn nǹkan yìí,+ Senakérúbù ọba Ásíríà wá, ó sì ya wọ Júdà. Ó dó ti àwọn ìlú olódi, ó fẹ́ wọlé kí ó sì gbà wọ́n.+

  • Àìsáyà 8:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Torí náà, wò ó! Jèhófà máa mú kí

      Ibú omi Odò ńlá* náà ya lù wọ́n,

      Ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.

      Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,

      Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,

       8 Ó sì máa rọ́ gba Júdà kọjá.

      Ó máa kún bò ó, ó sì máa gbà á kọjá, ó máa kún dé ọrùn rẹ̀;+

      Ìyẹ́ rẹ̀ tó nà jáde máa bo ìbú ilẹ̀ rẹ,

      Ìwọ Ìmánúẹ́lì!”*+

  • Àìsáyà 10:28-32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ó ti wá sí Áyátì;+

      Ó ti gba Mígírónì kọjá;

      Míkímáṣì+ ló kó ẹrù rẹ̀ sí.

      29 Wọ́n ti kọjá níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò;

      Gébà+ ni wọ́n sùn mọ́jú;

      Rámà gbọ̀n rìrì, Gíbíà + ti Sọ́ọ̀lù ti sá lọ.+

      30 Kígbe kí o sì pariwo, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù!

      Fiyè sílẹ̀, ìwọ Láíṣà!

      O gbé, ìwọ Ánátótì!+

      31 Mádíménà ti sá lọ.

      Àwọn tó ń gbé Gébímù ti wá ibì kan fara pa mọ́ sí.

      32 Lónìí yìí gan-an, ó máa dúró ní Nóbù.+

      Ó mi ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ sí òkè ọmọbìnrin Síónì,

      Òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.

  • Àìsáyà 33:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Àwọn ojú pópó dá páropáro;

      Ẹnì kankan ò gba àwọn ojú ọ̀nà kọjá.

      Ó* ti da májẹ̀mú;

      Ó ti kọ àwọn ìlú náà sílẹ̀;

      Kò ka ẹni kíkú sí.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́