ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 15:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “Màá sọ ọ́ di odi bàbà tó lágbára sí àwọn èèyàn yìí.+

      Ó dájú pé wọ́n á bá ọ jà,

      Àmọ́ wọn ò ní borí* rẹ,+

      Torí mo wà pẹ̀lú rẹ, láti gbà ọ́ àti láti dá ọ sílẹ̀,” ni Jèhófà wí.

  • Jeremáyà 32:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì dó ti Jerúsálẹ́mù, wòlíì Jeremáyà sì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ ní ilé* ọba Júdà.

  • Jeremáyà 33:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, nígbà tó ṣì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ pé:

  • Jeremáyà 37:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Nítorí náà, Ọba Sedekáyà ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójúmọ́ láti òpópónà àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú náà fi tán.+ Jeremáyà kò sì kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.

  • Jeremáyà 39:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí náà, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ àti Nebuṣásíbánì tó jẹ́ Rábúsárísì* àti Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Rábúmágì* pẹ̀lú gbogbo èèyàn sàràkí-sàràkí ọba Bábílónì ránṣẹ́ 14 pé kí wọ́n mú Jeremáyà jáde kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì fà á lé ọwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ láti mú un wá sí ilé rẹ̀. Torí náà, ó ń gbé ní àárín àwọn èèyàn náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́