-
Jeremáyà 43:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá ránṣẹ́ pe Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí mo fi pa mọ́ yìí, á sì na àgọ́ ìtẹ́ rẹ̀ lé wọn lórí.+ 11 Ó máa wọlé, á sì kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹni tó bá yẹ fún àjàkálẹ̀ àrùn ni àjàkálẹ̀ àrùn máa pa, ẹni tó bá yẹ fún oko ẹrú ló máa lọ sí oko ẹrú, ẹni tó bá sì yẹ fún idà ni idà máa pa.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 32:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Idà ọba Bábílónì yóò wá sórí rẹ.+
-