8 “‘Àmọ́ ní ti ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ,+ ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Bákan náà ni màá ṣe sí Sedekáyà+ ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó wà ní ilẹ̀ yìí àti àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
21 Màá sì fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn* àti lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì+ tó ṣígun kúrò lọ́dọ̀ yín.’+
17 Lẹ́yìn náà, Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pè é, ọba sì bi í ní ìbéèrè ní bòókẹ́lẹ́ nínú ilé* rẹ̀.+ Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kankan wà látọ̀dọ̀ Jèhófà?” Jeremáyà fèsì pé, “Ó wà!” ó sì fi kún un pé, “A ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Bábílónì!”+
18 Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+