-
2 Àwọn Ọba 25:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 14 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn ìkóná àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà+ ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà+ ṣe. 16 Ní ti àwọn òpó méjèèjì àti Òkun pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, bàbà tó wà lára gbogbo àwọn nǹkan èlò yìí kọjá wíwọ̀n.+
-