-
Diutarónómì 12:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí o máa lé kúrò run,+ tí o sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn, 30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+ 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
-