2 “Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ. 3 Lẹ́yìn náà, fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù,+ ọba Móábù,+ ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ọba Tírè+ àti ọba Sídónì+ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó wá sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà.