11 Mósè wá bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,*+ ó sọ pé: “Jèhófà, kí ló dé tí wàá fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ, lẹ́yìn tí o fi agbára ńlá àti ọwọ́ agbára mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì?+
9 Sámúẹ́lì wá mú ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó ṣì ń mu ọmú, ó sì fi rú odindi ẹbọ sísun+ sí Jèhófà; Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jèhófà sì dá a lóhùn.+