8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.
28Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+
3 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú ẹbọ rú èéfín ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,* ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.
31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+