-
2 Àwọn Ọba 24:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+ 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.
-
-
Jeremáyà 24:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Lẹ́yìn náà, Jèhófà fi apẹ̀rẹ̀ méjì tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú wọn níwájú tẹ́ńpìlì Jèhófà hàn mí. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì mú Jekonáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ irin.* Ó kó wọn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.+
-
-
Dáníẹ́lì 1:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+
3 Ọba wá pàṣẹ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pé kó mú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wá, títí kan àwọn ọmọ ọba àti ọmọ àwọn èèyàn pàtàkì.+
-