-
Diutarónómì 28:53-57Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.
54 “Ọkùnrin tí kò lágbaja rárá, tó sì lójú àánú láàárín rẹ kò tiẹ̀ ní ṣàánú arákùnrin rẹ̀ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ́ kù, 55 kò sì ní fún wọn ní ìkankan lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jẹ, torí kò ní nǹkan kan mọ́ nítorí bí àwọn ọ̀tá ṣe dó tì ọ́ àti bí wàhálà tí wọ́n kó bá àwọn ìlú+ rẹ ṣe pọ̀ tó. 56 Obìnrin tí kò lágbaja tó sì lójú àánú láàárín rẹ, tí kò tiẹ̀ ní ronú rárá láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ kanlẹ̀ torí pé kò lágbaja+ kò ní ṣàánú ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀, 57 àní kò ní ṣàánú àwọn ohun tó jáde láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lẹ́yìn tó bímọ àtàwọn ọmọ tó bí. Ó máa jẹ wọ́n níkọ̀kọ̀ torí bí nǹkan ṣe máa le nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá àwọn ìlú rẹ.
-