ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 28:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+

  • Diutarónómì 28:36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Jèhófà máa lé ìwọ àti ọba tí o bá fi jẹ lórí ara rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀,+ o sì máa sin àwọn ọlọ́run míì níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta+ ṣe.

  • 2 Àwọn Ọba 24:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

  • 2 Àwọn Ọba 25:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+

  • Ìdárò 4:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Èémí wa, ẹni àmì òróró Jèhófà,+ ni wọ́n ti mú nínú kòtò ńlá wọn,+

      Ẹni tí a sọ nípa rẹ̀ pé: “Abẹ́ òjìji rẹ̀ la ó máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”

  • Ìsíkíẹ́lì 12:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+

  • Dáníẹ́lì 1:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ọba wá pàṣẹ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pé kó mú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wá, títí kan àwọn ọmọ ọba àti ọmọ àwọn èèyàn pàtàkì.+

  • Dáníẹ́lì 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Àwọn kan wà lára wọn tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà* Júdà: Dáníẹ́lì,*+ Hananáyà,* Míṣáẹ́lì* àti Asaráyà.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́