19 Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan,+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn;+ màá mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn,+ màá sì fún wọn ní ọkàn ẹran,+ 20 kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, kí wọ́n sì máa rìn nínú rẹ̀. Wọ́n á wá di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.”’