-
Ìsíkíẹ́lì 45:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 “‘Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà bí ogún,+ kí ẹ mú ìpín kan tó jẹ́ mímọ́ lára ilẹ̀ náà wá fún Jèhófà láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.+ Gbogbo agbègbè* rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́. 2 Apá kan nínú ilẹ̀ náà tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba yóò wà fún ibi mímọ́, ìwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìgbọ̀nwọ́ níbùú àti lóòró,+ yóò sì ní ibi ìjẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.+
-